Lẹyin iku Cromwell, ti aye ọlọba si ti pada bọ sipo, Ọba Charles Keji ṣe ifilọlẹ ṣiṣe Ade Wura tuntun miran, ati Ade St. Ṣugbọn Ade naa di yíyọ ni 1600 lẹyin ti Oliver Cromwell pa Ọba Charles Kinni. Oju nnkan iṣẹmbaye to jẹ mimọ ni wọn fi n wo Ade Ọba Edward, ti wọn si n lo o fun ọgọọrọ ọdun lasiko ifinijọba. Wọn ṣe apejuwe rẹ to wọ Ade ni ọọrundunrun kọkanla ti Bayeux Tapestry. Edward to jẹ ẹni Ọlọrun ti awọn eeyan a maa lọ ti ipasẹ rẹ jẹwọ ẹṣẹ wọn fun Ọlọrun. Wọn fi orukọ rẹ sọri eyi ti wọn ti ṣe tipẹ tipẹ to jẹ ti Ọba ẹkun Anglo Saxon to si tun jẹ ẹni mimọ julọ, St. Wọn ṣe Ade naa fun Charles Keji ni ọdun 1661. Wọn ko gbogbo wọn jọ lọna giga soke rẹ fi jọju gidi pẹlu enamel ati wura.Īwọn okuta to wa lara Ade naa maa n jẹ eyi to ṣee yọ tẹlẹ ti wọn si maa n ya a fun lilo paapaa fun awọn ayẹyẹ ifinijọba. Ade naa ni okuta iyebiye irinwo o le mẹrinlelogoji (444) ati oniruuru okuta iyebiye - to fi mọ awọn okuta to wọn bii: Sapphires, rubbies, amethysts ati topaz, bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wọn lo ni awọ buluu fẹẹrẹfẹ tabi okuta buluu to tun fara yi awọ ewe.
0 Comments
Leave a Reply. |
AuthorWrite something about yourself. No need to be fancy, just an overview. ArchivesCategories |